DR Congo boat accident: Ọkọ̀ ojú omi dojúdé lágbami, èèyàn 40 kú, 167 míràn di àwátì

Àkọlé àwòrán,

Korami Mopole wa lara awọn to moribọ ninu ijamba ọkọ oju omi naa.

Awọn kan ti ori ko yọ ninu ijamba ọkọ oju omi to ṣẹlẹ ni Democratic Republic of Congo ti n sọ iriri wọn fun BBC nipa bi wọn ṣe moribọ.

 »Gbogbo ara mi, yatọ si ori mi, lo wa ninu omi. Mo rọ mọ pako ara ọkọ oju omi naa to kan ku titi tawọn to gbe ọkọ oju omi fi wa doola mi »

Bẹẹ ni Korami Mopole ṣe ṣe apejuwe nkan t’oju rẹ ri ninu ijamba ọkọ ou omi taa n wi yii.

Oku eeyan ogoji ni wọn ti ri bayii ti awọn to n gbiyanju ati doola ẹmi nibẹ si ni awọn ṣi n wa eeyan mẹtadinlaadọsan an.

Ohun taa gbọ ni pe ọkọ naa gbe ẹru to kọja agbara rẹ.

Awọn eeyan to le ni ọọdunrun ati ẹru lo wa ninu ọkọ naa to n gbe ero lori odo Congo gẹgẹ bi ajọ aladani kan to n ṣeto idoola awọn eeyan ṣe sọ.

‘Nṣe ni mo rọ mọ ara ọkọ oju omi naa bi o ti ṣe n ri sinu omi’

Eeyan kan toun naa moribọ ninu ijamba yi to waye lọjọ Ẹti, Michael Busakasa sọ pe ko pẹ to gbera kuro leti omi ni Mbandaka lawọn to n dari ọkọ naa ri pe ẹru to gbe fi sẹgbẹ kan.

O ni wọn bẹrẹ si ni ko awọn apo simẹnti ti wọn ko sẹgbẹ kan ti o baa le duro daada.

Amọ pabo ni igbiyanju yi ja si.

Lẹyin igba naa ni wọn gbe ọkọ kekere kan ti ọkọ oju omi naa gbe sinu kuro.

O sọ pe  »kete ti wọn ṣe eleyi ni ọkọ naa ba bẹrẹ si ni wọmi lọ. »

Ọgbẹni Busakasa iya rẹ ati aburo rẹ obinrin n gbe baba wọn pada lọ si ile lati ile iwosan ni.

Gbogbo wọn pata lori ko yọ ninu ijamba ọkọ oju omi to tẹri yi.

 »Mi o mọ bi wn ṣe n wẹdo amọ iwaju ni gbogbo wa wa ninu ọkọ oju omi naa.Apa iwaju yi ṣi n lefo lori omi eyi lo si mu kawọn to wa doola wa ribi ko wa yọ ninu ijamba yi »

 »aikọbi ara ijọba si ririn loru ati lilo awọn ọkọ oju omi ti ko lalaafia » lo fa ijamba naa

Ọkọ oju omi jẹ nkan tawn eeyan fi n ṣe irinṣẹ tori oju ọna ti ko da lorileede DR Congo.

Amọ ijamba yi a maa waye tori pe wọn a maa ko ero pupọ ati pe wọn a maa rin lọpọ igba laarin oru.

Pupọ awọn to n wọ ọkọ oju omi yi ni kii lo aṣọ idaabo taa mọ si life jacket.

Awọn alaṣẹ sọ pe ọkọ yi gbero ni itako ofin pẹlu bo ṣe rin lalẹ.

Olori awọn ẹgbẹ alatako to si tun jẹ oludije ninu idibo aarẹ to n bọ ni oṣu Kejila Moise Katumbi sọ pe  »ibanujẹ nla ni iṣẹlẹ yi jẹ fun oun »

O sọ pe o waye nitori  »aikọbi ara ijọba si ririn loru ati lilo awọn ọkọ oju omi ti ko lalaafia »

Ileeṣẹ redio to lajọṣepọ pẹlu ajọ isọkan agbaye,Radio Okapi jabọ pe ijọba agbegbe Equateur ti ijamba yi ti waye sọ pe awọn yoo pese atilẹyin itọju ọkan fawọn ọmọ de to afarapa tabi to padanu obi ninu ijamba yi.

Ileeṣẹ redio naa sọ pe o le ni okueeyan ogoji ti wọn ti ri bayii amọ ajọaladani Conscious Generation s pe eeyan aadọta ni wọn ti ri.

Eeyan kan ti ori ko yọ sọ pe ọkọ oju omi naa to gbera kuro lati Mbandaka lọ si agbegbe Bolomba ni iuw oorun ariwa Equateur ṣadede duro to si bẹrẹ si ni dẹgbẹ tori pe o ko ẹru to kọja agbara rẹ.

Gẹgẹ bi ẹni yi ṣe sọ,nigba tawọn to n dari ọkọ naa gbiyanju lati dari rẹ pada lo yi da somi tawọn eeyan ati ẹru to ko si bọ sodo.

Lọjọ Aiku igbakeji alakoso agbegbe Equateur pese aṣọ ati posi ti wọn yoo fi ṣeto isinku awọn to ba ijamba yi lọ.

Crédit: Lien source

Les commentaires sont fermés.